1 Kings 8:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni ọba ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli péjọ níwájú Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, wọ́n sì fi ọpọlọpọ aguntan ati mààlúù tí ẹnikẹ́ni kò lè kà rúbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀ niwaju apoti-ẹri, nwọn nfi agutan ati malu ti a kò le mọ̀ iye, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ rubọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti Sólómónì ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí-ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rúbọ.