1 Kings 8:50 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si darijì awọn enia rẹ ti o ti dẹṣẹ si ọ, ati gbogbo irekọja wọn ninu eyiti nwọn ṣẹ̀ si ọ, ki o si fun wọn ni ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ki nwọn ki o le ṣãnu fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o sì dáríjìn àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn;