1 Kings 8:56 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibukún ni fun Oluwa ti o ti fi isimi fun Israeli enia rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ṣe ileri: kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo ileri rere rẹ̀ ti o ti ṣe lati ọwọ Mose, iranṣẹ rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìbùkún ni fún OLÚWA tí ó ti fi ìsinmi fún Ísírẹ́lì, ènìyàn rẹ̀ bí ó ti ṣèlérí. Kò sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ìlérí rere tí ó ti ṣe láti ọwọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀ wá.