1 Kings 8:59 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí OLUWA Ọlọrun wa ranti adura mi yìí ati gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí mo bẹ̀ níwájú rẹ̀ yìí tọ̀sán-tòru, kí ó máa ti èmi iranṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà gbogbo, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀ pẹlu; máa tì wá lẹ́yìn bí ó bá ti tọ́ lojoojumọ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si jẹ ki ọ̀rọ mi wọnyi, ti mo fi bẹ̀bẹ niwaju Oluwa, ki o wà nitosi, Oluwa Ọlọrun wa, li ọsan ati li oru, ki o le mu ọ̀ran iranṣẹ rẹ duro, ati ọ̀ran ojojumọ ti Israeli, enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti kí ó sì jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí, tí mo ti gbà ní àdúrà níwájú OLÚWA, kí ó wà nítòsí OLÚWA Ọlọ́run wa ní ọ̀sán àti ní òru, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró àti ọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àìní wa ojoojúmọ́,