1 Kings 8:63 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni fi ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) mààlúù, ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni òun ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe ya ilé OLUWA náà sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si ru ẹbọ ọrẹ-alafia, ti o ru si Oluwa, ẹgbã-mọkanla malu, ati ọkẹ mẹfa àgutan. Bẹ̃ni ọba ati gbogbo awọn ọmọ Israeli yà ile Oluwa si mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì rú ẹbọ ọrẹ àlàáfíà sí OLÚWA: ẹgbàá mọ́kànlá (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn omọ Ísírẹ́lì ya ilé OLÚWA sí mímọ́.