1 Kings 8:64 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan náà, ọba ya ààrin gbùngbùn àgbàlá tí ó wà níwájú ilé ìsìn sí mímọ́. Níbẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ọ̀rá ẹran tí ó fi rú ẹbọ alaafia; nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA kéré jù fún àpapọ̀ gbogbo àwọn ẹbọ wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọ̀jọ na ni ọba yà agbàla ãrin ti mbẹ niwaju ile Oluwa si mimọ́: nitori nibẹ ni o ru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ọrẹ-onjẹ, ati ẹbọ-ọpẹ: nitori pẹpẹ idẹ ti mbẹ niwaju Oluwa kere jù lati gba ọrẹ-sisun ati ọrẹ-ọnjẹ, ati ọ̀ra ẹbọ-ọpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárin tí ń bẹ níwájú ilé OLÚWA sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ ọrẹ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú OLÚWA kéré jù láti gba ọrẹ ṣíṣun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.