1 Kings 8:65 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe Àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ níbẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan láti Ẹnu Ọ̀nà Hamati títí dé odò kékeré Ijipti ni wọ́n péjọ níwájú OLUWA fún ọjọ́ meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li àkoko na, Solomoni papejọ kan, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ajọ nla-nlã ni, lati iwọ Hamati titi de odò Egipti, niwaju Oluwa Ọlọrun wa, ijọ meje on ijọ meje, ani ijọ mẹrinla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe àpèjọ nígbà náà, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hámátì títí dé odò Éjíbítì. Wọ́n sì sàjọyọ̀ níwájú OLÚWA Ọlọ́run wa ní ijọ́ méje àti ijọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.