1 Kings 8:66 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹjọ Solomoni tú àwọn eniyan náà ká lọ sí ilé wọn. Gbogbo wọn ni wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì pada sílé pẹlu inú dídùn; nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fún àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ kẹjọ o rán awọn enia na lọ: nwọn si sure fun ọba, nwọn si lọ sinu agọ wọn pẹlu ayọ̀ ati inu-didun, nitori gbogbo ore ti Oluwa ti ṣe fun Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fun Israeli, enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ. Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí OLÚWA ti ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.