1 Kings 9:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì ọba sì fi ogún ìlú ní Gálílì fún Hírámù ọba Tírè, nítorí tí Hírámù ti bá a wá igi kédárì àti igi fírì àti wúrà gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìfẹ́ rẹ̀.