1 Kings 9:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdí àwọn asìnrú ti Sólómónì ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé OLÚWA àti ààfin òun tìkárarẹ̀; Mílò, odi Jérúsálẹ́mù, Hásórì, Mégídò àti Gésérì.