1 Kings 9:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
(Farao, ọba Ijipti ti gbógun ti ìlú Geseri ó sì dáná sun ún, ó pa gbogbo àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Ó fi ìlú náà ṣe ẹ̀bùn igbeyawo fún ọmọ rẹ̀ obinrin, nígbà tí ó fẹ́ Solomoni ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Farao, ọba Egipti ti goke lọ, o si ti kó Geseri, o si ti fi iná sun u, o si ti pa awọn ara Kenaani ti ngbe ilu na, o si fi ta ọmọbinrin rẹ̀, aya Solomoni li ọrẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fáráò ọba Éjíbítì sì ti kọlu Gésérì, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kénánì tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Sólómónì lọ́rẹ.