1 Kings 9:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati àwọn ìlú tí ó ń kó àwọn ohun èlò rẹ̀ pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí ó ń kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ń gbé, ati gbogbo ilé yòókù tí ó wu Solomoni láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lẹbanoni, ati ní àwọn ibòmíràn ninu ìjọba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo ilu iṣura ti Solomoni ni, ati ilu kẹkẹ́ rẹ̀, ati ilu fun awọn ẹlẹsin rẹ̀, ati eyiti Solomoni nfẹ lati kọ́ ni Jerusalemu, ati ni Lebanoni, ati ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Sólómónì ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ní Lébánónì àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso.