1 Kings 9:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Solomoni kò fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹrú. Àwọn ni ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun, ati olórí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀; àwọn ni balogun rẹ̀, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀; àwọn ni ọ̀gá àwọn tí ń darí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ninu awọn ọmọ Israeli, Solomoni kò fi ṣe ẹrú, ṣugbọn nwọn jẹ awọn ologun ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn balogun rẹ̀, ati awọn olori kẹkẹ́ rẹ̀ ati ti awọn ẹlẹsin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, Sólómónì kò fi ẹnìkankan ṣe ẹrú nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; àwọn ni ológun rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.