1 Kings 9:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, ọmọ ọba Farao, iyawo Solomoni kó kúrò ní ìlú Dafidi, ó lọ sí ilé tí Solomoni kọ́ fún un. Lẹ́yìn náà ni Solomoni kọ́ ìlú Milo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọmọbinrin Farao goke lati ilu Dafidi wá si ile rẹ̀, ti Solomoni kọ́ fun u: nigbana ni o kọ́ Millo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí ọmọbìnrin Fáráò ti gòkè láti ìlú Dáfídì wá sí ààfin tí Sólómónì kọ́ fún un, nígbà náà ni ó kọ́ Mílò.