1 Kings 9:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó wí fún un pé, “Mo ti gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ, mo sì ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́. Ibẹ̀ ni wọn óo ti máa sìn mí títí lae. N óo máa mójú tó o, n óo sì máa dáàbò bò ó nígbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si wi fun u pe, Mo ti gbọ́ adura rẹ ati ẹ̀bẹ rẹ, ti iwọ ti bẹ̀ niwaju mi, mo ti ya ile yi si mimọ́, ti iwọ ti kọ́, lati fi orukọ mi sibẹ titi lai; ati oju mi ati ọkàn mi yio wà nibẹ titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì wí fún un pé: “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.