1 Kings 9:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
n óo fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ ní Israẹli, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, pé arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li emi o fi idi itẹ́ ijọba rẹ mulẹ lori Israeli titi lai, bi mo ti ṣe ileri fun Dafidi baba rẹ, wipe, Iwọ kì yio fẹ ọkunrin kan kù lori itẹ́ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dáfídì baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’