1 Kings 9:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ìwọ tabi arọmọdọmọ rẹ bá yapa kúrò lẹ́yìn mi, tí ẹ bá ṣe àìgbọràn sí àwọn òfin ati ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fún yín, tí ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi ẹnyin o ba yipada lati mã tọ̀ mi lẹhin, ẹnyin, tabi awọn ọmọ nyin, bi ẹnyin kò si pa ofin mi mọ́, ati aṣẹ mi ti mo ti fi si iwaju nyin, ṣugbọn bi ẹ ba lọ ti ẹ si sìn awọn ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin Ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,