1 Kings 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
n óo mú àwọn ọmọ Israẹli kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn, n óo sì kọ ilé ìsìn tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sílẹ̀. Gbogbo ọmọ Israẹli yóo di ẹni àmúpòwe ati ẹlẹ́yà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni emi o ké Israeli kuro ni ilẹ ti emi fi fun wọn; ati ile yi, ti mo ti yà si mimọ́ fun orukọ mi li emi o gbe sọnù kuro niwaju mi; Israeli yio si di owe ati ifiṣẹsin lãrin gbogbo orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nígbà náà ni èmi yóò ké Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ tí èmi fi fún wọn, èmi yóò sì kọ ilé yìí tí èmi ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò sì di òwe àti ìmúṣẹ̀sín láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè.