1 Kings 9:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ilé yìí yóo di òkìtì àlàpà, yóo sì di ohun àwòyanu ati ẹ̀gàn fún gbogbo ẹni tí ó bá ń rékọjá lọ. Wọn óo máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati ilé yìí?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ile yi, ti o ga, ẹnu o si ya olukuluku ẹniti o kọja lẹba rẹ̀, yio si pòṣe: nwọn o si wipe; ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi ati si ile yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ilé yìí tí ó ga, ẹnu yóò sì ya olúkúlùkù ẹni tí ó kọjá lẹ́bàá rẹ̀, yóò sì pòṣé, wọn ó sì wí pé, ‘Èéṣe tí OLÚWA fi ṣe irú nǹkan yìí sí ilẹ̀ yìí àti ilé yìí?’