1 Peter 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ìwa nyin larin awọn Keferi kí o dara; pe, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere nyin, ti nwọn o mã kiyesi, ki nwọn ki o le mã yìn Ọlọrun logo li ọjọ ìbẹwo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ìwà yín láàrin àwọn aláìkọlà dára; pé, bí wọn ti ń sọ̀rọ̀ yín bí olùṣe búburú, nípa iṣẹ́ rere yín tí wọn ó máa kíyèsí, kí wọ́n lè máa yin Ọlọ́run lógo lọ́jọ́ ti òun ba bẹ̀ wá wò.