1 Peter 2:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ẹ̀yẹ wo ni ó wà ninu pé ẹ ṣe àìdára, wọ́n lù yín, ẹ wá faradà á? Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ jìyà tí ẹ faradà á, èyí jẹ́ ẹ̀yẹ lójú Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣẹ̀ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sũru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere; ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sũru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ògo kínni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba sẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, èyí ní ìgbóríyìn-fún lọ́dọ̀ Ọlọ́run.