1 Peter 3:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kírísítì bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń bèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.