1 Peter 3:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogun ìbùkún.