1 Peter 4:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnikẹni ba nsọ̀rọ, ki o mã sọ bi ọ̀rọ Ọlọrun; bi ẹnikẹni ba nṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fifun u: ki a le mã yìn Ọlọrun logo li ohun gbogbo nipa Jesu Kristi, ẹniti ogo ati ìjọba wà fun lai ati lailai. Amin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, kí í ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fifún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. (Àmín).