1 Peter 4:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọn bá ń fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí orúkọ Kristi, ẹ ṣe oríire, nítorí Ẹ̀mí tí ó lógo nnì, Ẹ̀mí Ọlọrun, ti bà lé yín lórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi a ba ngàn nyin nitori orukọ Kristi, ẹni ibukun ni nyin; nitori Ẹmí ogo ati ti Ọlọrun bà le nyin: nipa tiwọn nwọn nsọ̀rọ rẹ̀ ni ibi, ṣugbọn nipa tinyin a nyìn i logo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kírísítì, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín (ní ọ̀dọ̀ tí wọn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ibi, ṣùgbọ́n ní ọ̀dọ̀ ti yín a yìn ín lógo.)