1 Peter 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí rẹ̀ ni a ṣe waasu ìyìn rere fún àwọn òkú, pé bí wọ́n bá tilẹ̀ gba ìdájọ́ bí gbogbo eniyan ti níláti gbà ninu ara, sibẹ wọn óo wà láàyè ninu ẹ̀mí nípa ti Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi li a sá ṣe wasu ihinrere fun awọn okú, ki a le ṣe idajọ wọn gẹgẹ bi enia nipa ti ara, ṣugbọn ki nwọn ki o le wà lãye si Ọlọrun nipa ti ẹmí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ní a ṣá ṣe wàásù ìyìn rere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láàyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.