1 Peter 5:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo, ti o ti pè nyin sinu ogo rẹ̀ ti kò nipẹkun ninu Kristi Jesu, nigbati ẹnyin ba ti jìya diẹ, On tikarãrẹ, yio si ṣe nyin li aṣepé, yio fi ẹsẹ nyin mulẹ, yio fun nyin li agbara, yio fi idi nyin kalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kírísítì Jésù, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkararẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀.