1 Peter 5:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrin yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáse, bí kò se tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ijẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìyè inú tí ó múra tan.