1 Samuel 1:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Elikana ati ìdílé rẹ̀ múra, wọ́n sì sin OLUWA. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbéra, wọ́n pada sí ilé wọn, ní Rama. Nígbà tí ó yá, Elikana bá Hana lòpọ̀, OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn wolẹ sìn niwaju Oluwa, nwọn pada wá si ile wọn si Rama: Elkana si mọ aya rẹ̀; Oluwa si ranti rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì díde ni kùtùkùtù òwúrọ̀, wọn wólẹ̀ sìn níwájú OLÚWA, wọn padà wa sí ilé wọn ni Rámà: Elikánà si mọ aya rẹ̀: OLÚWA sì rántì rẹ̀.