1 Samuel 1:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, àkókò tó fún Elikana ati ìdílé rẹ̀ láti lọ sí Ṣilo, láti lọ rú ẹbọ ọdọọdún, kí Elikana sì san ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ fún OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na Elkana, ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀, goke lọ lati rubọ ọdun si Oluwa, ati lati san ileri ifẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin náà Elikánà, àti gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, gòkè lọ láti rúbọ ọdún sí OLÚWA, àti láti sán ẹ̀jẹ́ rẹ̀.