1 Samuel 1:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Hana kò bá wọn lọ. Ó wí fún ọkọ rẹ̀ pé, “Bí mo bá ti gba ọmú lẹ́nu ọmọ yìí ni n óo mú un lọ sí ilé OLUWA, níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí ọjọ́ ayé rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Hanna ko goke lọ; nitori ti o wi fun ọkọ rẹ̀ pe, o di igbati mo ba gba ọmu lẹnu ọmọ na, nigbana li emi o mu u lọ, ki on ki o le fi ara han niwaju Oluwa, ki o si ma gbe ibẹ titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Hánà kò gòkè lọ; nítorí tí ó sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ó di ìgbà tí mo bá gba ọmú lẹ́nu ọmọ náà, nígbà náà ni èmi yóò mú un lọ, kí òun lè fi ara hàn níwájú OLÚWA, kí ó sí máa gbé ibẹ̀ títí láé.”