1 Samuel 1:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Elikana dá a lóhùn pé, “Ṣe bí ó bá ti tọ́ ní ojú rẹ. Dúró ní ilé, títí tí o óo fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀. Kí OLUWA jẹ́ kí o lè mú ìlérí rẹ ṣẹ.” Hana bá dúró ní ilé, ó ń tọ́jú ọmọ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elkana ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ṣe eyi ti o tọ li oju rẹ; duro titi iwọ o fi gba ọmu li ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ki Oluwa ki o sa mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ. Bẹ̃li obinrin na si joko, o si fi ọmu fun ọmọ rẹ̀ titi o fi gbà a lẹnu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Elikánà ọkọ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ. Dúró títí ìwọ yóò fi gba ọmú lẹ́nu rẹ̀; ṣùgbọ́n kí OLÚWA ṣáà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin náà sì jókòó, ó sì fi ọmú fún ọmọ rẹ̀ títí ó fi gbà á lẹ́nu rẹ̀.