1 Samuel 1:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó mú un lọ́wọ́ lọ sí Ṣilo. Nígbà tí ó ń lọ, ó mú akọ mààlúù ọlọ́dún mẹta kan lọ́wọ́, ati ìyẹ̀fun ìwọ̀n efa kan, ati ọtí waini ẹ̀kún ìgò aláwọ kan. Ó sì mú Samuẹli lọ sí Ṣilo ní ilé OLUWA, ọmọde ni Samuẹli nígbà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si gba ọmu li ẹnu rẹ̀, o si mu u goke lọ pẹlu ara rẹ̀, pẹlu ẹgbọrọ malu mẹta, ati iyẹfun efa kan, ati igo ọti-wain kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọmọde.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì gba ọmú lẹ́nu rẹ̀, ó sì mú un gòkè lọ pẹ̀lú ara rẹ̀. Pẹ̀lú ẹgbọrọ màlúù mẹ́ta, àti ìyẹ̀fun éfà kan, àti ìgò ọti-wáìnì kan, ó sì mú un wá sí ilé OLÚWA ní Ṣílò: ọmọ náà ṣì wà ní ọmọdé.