1 Samuel 1:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdọọdún ni Elikana máa ń ti Ramataimu-sofimu lọ sí Ṣilo láti lọ sin OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati láti rúbọ sí i. Hofini ati Finehasi, àwọn ọmọ Eli, ni alufaa OLUWA níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọdun lati sìn ati lati ṣe irubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ọmọ Eli mejeji Hofni ati Finehasi alufa Oluwa, si wà nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí OLÚWA alágbára jùlọ ní Ṣílò, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì ti jẹ́ àlùfáà OLÚWA.