1 Samuel 1:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Penina, orogún Hana, a máa fín in níràn gidigidi, kí ó baà lè mú un bínú, nítorí pé OLUWA kò fún un ní ọmọ bí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Orogún rẹ̀ pẹlu a si ma tọ́ ọ gidigidi lati mu u binu, nitoriti Oluwa ti se e ni inu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé OLÚWA ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín in níràn láti lè mú kí ó bínú.