1 Samuel 1:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí wọ́n jẹ, tí wọ́n mu tán, ninu ilé OLUWA, ní Ṣilo, Hana dìde. Eli, alufaa wà ní ìjókòó lórí àpótí, lẹ́bàá òpó ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Hanna si dide lẹhin igbati wọn jẹ, ti nwọn si mu tan ni Ṣilo. Eli alufa si joko lori apoti li ẹba opó tempili Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣílò, Hánà dìde wá ṣíwájú OLÚWA. Nígbà náà, Élì àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLÚWA ní ibi tí ó máa ń jókòó.