1 Samuel 10:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Samuẹli mú ìgò òróró olifi kan, ó tú u lé Saulu lórí. Ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì wí fún un pé, “OLUWA fi àmì òróró yàn ọ́ ní olórí àwọn eniyan Israẹli. Ohun tí yóo sì jẹ́ àmì tí o óo fi mọ̀ pé OLUWA ló yàn ọ́ láti jọba lórí àwọn eniyan rẹ̀ nìyí:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SAMUELI si mu igo ororo, o si tu u si i li ori, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si wipe, Kò ṣepe nitoriti Oluwa ti fi ororo yàn ọ li olori ini rẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Ṣọ́ọ̀lù. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “OLÚWA kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olóri í lórí ohun ìní rẹ̀?