1 Samuel 10:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i bí ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ pẹlu àwọn wolii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kiṣi? Àbí Saulu náà ti di wolii ni?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ ri pe o nsọtẹlẹ larin awọn woli, awọn enia si nwi fun ara wọn pe, Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ rí i tó ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àwọn wòlíì, wọ́n bi ara wọn, “Kí ni ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Kíṣì yìí. Ṣé Ṣọ́ọ̀lù wà lára àwọn wòlíì ní?”