1 Samuel 10:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?” Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arakunrin Saulu kan si wi fun u ati fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Nibo li ẹnyin ti lọ? On si wipe, lati wá awọn kẹtẹkẹtẹ ni: nigbati awa ri pe nwọn kò si nibi kan, awa si tọ Samueli lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí, arákùnrin baba Ṣọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?” Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Sámúẹ́lì.