1 Samuel 10:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, On ti sọ fun wa dajudaju pe, nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ nã. Ṣugbọn ọ̀ran ijọba ti Samueli sọ, on kò sọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Sámúẹ́lì sọ nípa ọba jíjẹ.