1 Samuel 10:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi mu Israeli goke ti Egipti wá, mo si gbà nyin kuro lọwọ́ awọn ara Egipti, ati kuro lọwọ́ gbogbo ijọba wọnni ti o pọn nyin loju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Èmi mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Éjíbítì àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’