1 Samuel 10:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, Ọlọrun tí ó gbà yín kúrò lọ́wọ́ ìṣòro ati ìyọnu. Ẹ wí fún mi pé, ‘Yan ẹnìkan, tí yóo jọba lórí wa.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin si kọ̀ Ọlọrun nyin loni, ẹniti on tikara rẹ́ ti gbà nyin kuro lọwọ́ gbogbo awọn ọta nyin, ati gbogbo wahala nyin; ẹnyin si ti wi fun u pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn awa nfẹ ki o fi ẹnikan jọba lori wa. Nisisiyi ẹ duro niwaju Oluwa nipa ẹyà nyin, ati nipa ẹgbẹgbẹrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú OLÚWA ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.”