1 Samuel 10:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí o bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi lónìí, o óo pàdé àwọn ọkunrin meji kan lẹ́bàá ibojì Rakẹli, ní Selisa, ní agbègbè Bẹnjamini. Wọn yóo sọ fún ọ pé, ‘Wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ẹ̀ ń wá. Nisinsinyii baba rẹ kò dààmú nítorí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, ṣugbọn ó ń jáyà nítorí rẹ, ó ń wí pé, “Kí ni n óo ṣe nípa ọmọ mi.” ’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati iwọ ba lọ kuro lọdọ mi loni, iwọ o ri ọkunrin meji li ẹba iboji Rakeli li agbegbe Benjamini, ni Selsa; nwọn o si wi fun ọ pe, Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá: si wõ, baba rẹ ti fi ọran ti kẹtẹkẹtẹ silẹ, o si kọ ominu nitori rẹ wipe, Kili emi o ṣe niti ọmọ mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rákélì ní Sélísà, ní agbégbé Bẹ́ńjámínì. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsìn yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń damú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípà ọmọ mi?” ’