1 Samuel 10:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu ki ẹya Benjamini sunmọ tosi nipa idile wọn, a mu idile Matri, a si mu Saulu ọmọ Kiṣi: nigbati nwọn si wá a kiri, nwọn kò si ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó kó ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣíwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Mátírì. Ní ìparí a sì yan Ṣọ́ọ̀lù ọmọ Kíṣì. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i,