1 Samuel 10:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.” Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹnyin kò ri ẹniti Oluwa yàn fun ara rẹ̀, pe, ko si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo enia na? Gbogbo enia si ho ye, nwọn si wipe, Ki Ọba ki o pẹ!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí OLÚWA ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàárin gbogbo àwọn ènìyàn.” Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”