1 Samuel 10:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn oníjàngbọ̀n kan dáhùn pé, “Báwo ni eléyìí ṣe lè gbà wá?” Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣugbọn Saulu kò sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ọmọ Beliali wipe, Ọkunrin yi yio ti ṣe gbà wa? Nwọn kẹgàn rẹ̀, nwọn ko si mu ọrẹ wá fun u. On si dakẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn oníjàgbọ̀n kan wí pé, “Báwo ni ẹni yìí yóò ṣe gbà wá?” Wọ́n kẹ́gan rẹ̀, wọn kò sì mú ẹ̀bùn wá fún un, ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù fọwọ́ lẹ́rán.