1 Samuel 10:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí o bá kúrò níbẹ̀, tí o sì ń lọ, o óo dé ibi igi oaku tí ó wà ní Tabori. O óo pàdé àwọn ọkunrin mẹta kan, tí wọ́n ń lọ rúbọ sí Ọlọrun ní Bẹtẹli. Ọ̀kan ninu wọn yóo fa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ mẹta lọ́wọ́, ekeji yóo kó burẹdi mẹta lọ́wọ́, ẹkẹta yóo sì gbé ìgò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si kọja lati ibẹ lọ, iwọ o si de pẹtẹlẹ Tabori, nibẹ li ọkunrin mẹta ti nlọ sọdọ Ọlọrun ni Beteli yio pade rẹ, ọkan yio mu, ọmọ ewurẹ mẹta lọwọ, ekeji yio mu iṣù akara mẹta, ati ẹkẹta yio mu igo ọti-waini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi Tábórì ńlá. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Bẹ́tẹ́lì yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, iṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹtà yóò mú ìgò wáìnì.