1 Samuel 10:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, lọ sí òkè Ọlọrun ní Gibea Elohimu, ní ibi tí ibùdó àwọn ọmọ ogun Filistini kan wà. Nígbà tí ó bá kù díẹ̀ kí ẹ dé ìlú náà, o óo pàdé ọ̀wọ́ àwọn wolii kan, tí wọn ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ibi pẹpẹ tí ó wà ní orí òkè. Wọn yóo máa ta hapu, wọn yóo máa lu aro, wọn yóo máa fọn fèrè, wọn yóo máa tẹ dùùrù, wọn yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin eyini iwọ o wá si oke Ọlọrun, nibiti ẹgbẹ ogun awọn Filistini wà; yio si ṣe, nigbati iwọ ba de ilu na, iwọ o si pade ẹgbẹ woli ti yio ma sọkalẹ lati ibi giga nì wá; nwọn o si ni psalteri, ati tabreti, ati fère, ati harpu niwaju wọn, nwọn o si ma sọtẹlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Fílístínì wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú líárì, támborí àti fèrè àti gìta níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àṣọtẹ́lẹ̀.