1 Samuel 11:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò yìí gan-an ni Saulu ń ti oko rẹ̀ bọ̀, pẹlu àwọn akọ mààlúù rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ tí gbogbo eniyan fi ń sọkún?” Wọ́n bá sọ ohun tí àwọn ará Jabeṣi sọ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiye si i, Saulu bọ̀ wá ile lẹhin ọwọ́ malu lati papa wá; Saulu si wipe, Ẽṣe awọn enia ti nwọn fi nsọkun? Nwọn si sọ ọ̀rọ awọn ọkunrin Jabeṣi fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà gan an ni Ṣọ́ọ̀lù padà wá láti pápá, pẹ̀lú màlúù rẹ̀, ó sì béèrè pé, “kín ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn? Èéṣe tí wọ́n fi ń sunkún?” Nígbà náà ni wọ́n tún sọ fún wọn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin Jábésì.