1 Samuel 11:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.” Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si mu malu meji, o rẹ́ wọn wẹwẹ, o si ran wọn si gbogbo agbegbe Israeli nipa ọwọ́ awọn onṣẹ na, wipe, Ẹnikẹni ti o wu ki o ṣe ti ko ba tọ Saulu ati Samueli lẹhin, bẹ̃ gẹgẹ li a o ṣe si malu rẹ̀. Ibẹ̀ru Oluwa si mu awọn enia na, nwọn si jade bi enia kanṣoṣo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì mú màlúù méjì, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó sì rán ẹyọyọ sí gbogbo Ísírẹ́lì nípa ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ náà, ó ní i ẹ kéde pé, “Èyí ni a ó ṣe sí màlúù ẹnikẹ́ni tí kò bá tọ Ṣọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì lẹ́yìn.” Nígbà náà ni ìbẹ̀rù OLÚWA sì mú àwọn ènìyàn, wọ́n sì jáde bí ènìyàn kan ṣoṣo.